Luku 11:39-44
39
Olúwa sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin Farisi a máa ń fọ òde ago àti àwopọ̀kọ́: ṣùgbọ́n, inú yín kún fún ìwà búburú àti ìrẹ́jẹ.
40
Ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹni tí ó ṣe èyí tí ń bẹ lóde, òun kò ha ṣe èyí tí ń bẹ nínú pẹ̀lú?
41
Nípa ohun ti inú yin, ki ẹ̀yin kúkú máa ṣe ìtọrẹ àánú nínú ohun tí ẹ̀yin ní, sì kíyèsi i, ohun gbogbo ni ó di mímọ́ fún yín.
42
“Ṣùgbọ́n ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, nítorí tí ẹ̀yin a máa san ìdámẹ́wàá minti àti irúgbìn, àti gbogbo ewébẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ ìdájọ́ àti ìfẹ́ Ọlọ́run: wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe, láìsí fi àwọn ìyókù sílẹ̀ láìṣe.
43
“Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin Farisi, àgàbàgebè! Nítorí tí ẹ̀yin fẹ́ ipò ọlá nínú Sinagọgu, àti ìkíni ní ọjà.
44
“Ègbé ni fún un yín,nítorí ẹ̀yin dàbí ibojì tí kò farahàn, tí àwọn ènìyàn sì ń rìn lórí rẹ̀ láìmọ̀.”
Settings