Skip to content
Lefitiku 3:6-12

Lefitiku 3:6-12

6
“ ‘Bí ó bá ṣe inú agbo ewúrẹ́ àti àgùntàn ni ó ti mú ọrẹ àlàáfíà wá fún Olúwa kí ó mú akọ tàbí abo tí kò ní àbùkù.
7
Bí ó bá ṣe pé ọ̀dọ́-àgùntàn ni ó mú, kí ó mú un wá síwájú Olúwa.
8
Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e lórí, kí ó sì pa á níwájú àgọ́ ìpàdé, kí àwọn ọmọ Aaroni wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà yí pẹpẹ ká.
9
Kí o sì mú wá nínú ẹbọ àlàáfíà náà, fún ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa; ọ̀rá rẹ̀ àti gbogbo ìrù rẹ̀ tí ó ní ọ̀rá, òun ni kí o mú kúrò súnmọ́ egungun ẹ̀yìn àti ọ̀rá tí ó bo ìfun lórí; àti gbogbo ọ̀rá tí ń bẹ lára ìfun.
10
Kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ń bẹ lẹ́bàá ìhà rẹ̀ àti ọ̀rá tí ó bo ẹ̀dọ̀, kí o yọ ọ́ jáde pẹ̀lú kíndìnrín.
11
Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.
12
“ ‘Bí ó bá ṣe pé ewúrẹ́ ni ó mú, kí ó mú un wá síwájú Olúwa.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options