Lefitiku 14:36-47
36
Àlùfáà yóò pàṣẹ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun má ṣe wà nínú ilé náà, kí ó tó lọ yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, kí ohunkóhun nínú ilé náà má bá à di àìmọ́. Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wọlé lọ láti yẹ ilé náà wò.
37
Yóò yẹ ààrùn náà wò, bí ààrùn náà bá ti wà lára ògiri ilé náà nípa àmì àwọ̀ ewé tàbí àmì pupa tí ó sì jinlẹ̀, ju ara ògiri lọ.
38
Àlùfáà yóò jáde kúrò nínú ilé náà, yóò sì ti ìlẹ̀kùn ilé náà pa fún ọjọ́ méje.
39
Àlùfáà yóò padà wá yẹ ilé náà wò ní ọjọ́ keje. Bí ààrùn náà bá ti tàn ká ara ògiri.
40
Àlùfáà yóò pàṣẹ kí a yọ àwọn òkúta tí ààrùn náà ti bàjẹ́ kúrò kí a sì kó wọn dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú.
41
Yóò sì mú kí wọ́n ha ògiri inú ilé náà yíká. Gbogbo ohun tí wọ́n fi rẹ́ ilé náà tí ó ti ha ni kí wọ́n kó dànù sí ibi tí a kà sí àìmọ́ lẹ́yìn ìlú náà.
42
Òkúta mìíràn ni kí wọ́n fi dípò àwọn tí a ti yọ dànù, kí wọ́n sì rẹ́ ilé náà pẹ̀lú àwọn ohun ìrẹ́lé tuntun.
43
“Bí ààrùn yìí bá tún farahàn lẹ́yìn tí a ti yọ àwọn òkúta wọ̀nyí tí a sì ti ha ilé náà ti a sì tún rẹ́ ẹ.
44
Àlùfáà yóò tún lọ yẹ̀ ẹ́ wò bí ààrùn náà bá tún gbilẹ̀ sí i nínú ilé náà: ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí, ilé náà jẹ́ aláìmọ́.
45
Wíwó ni kí a wó o, gbogbo òkúta ilé náà, àwọn igi àti gbogbo ohun tí a fi rẹ́ ẹ ni kí a kó jáde nínú ìlú sí ibi tí a kà sí àìmọ́.
46
“Ẹni tí ó bá wọ inú ilé náà lẹ́yìn tí a ti tì í, yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
47
Ẹni tí ó bá sùn nínú ilé náà tàbí tí ó bá jẹun nínú rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀.
Settings