Lefitiku 13:50-59
50
Àlùfáà yóò yẹ ẹ̀tẹ̀ náà wò, yóò sì pa gbogbo ohun tí ẹ̀tẹ̀ náà ti ràn mọ́ fún ọjọ́ méje.
51
Ní ọjọ́ keje kí ó yẹ̀ ẹ́ wò bí ààrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá ràn ká ara aṣọ tàbí irun àgùntàn, aṣọ híhun tàbí awọ, bí ó ti wù kí ó wúlò tó, ẹ̀tẹ̀ apanirun ni èyí jẹ́, irú ohun bẹ́ẹ̀ kò mọ́.
52
Ó gbọdọ̀ sun aṣọ náà tàbí irun àgùntàn náà, aṣọ híhun náà tàbí awọ náà ti ó ni ààrùn kan lára rẹ̀ ni iná torí pé ààrùn ẹ̀tẹ̀ tí í pa ni run ni. Gbogbo nǹkan náà ni ẹ gbọdọ̀ sun ní iná.
53
“Ṣùgbọ́n bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò tí ẹ̀tẹ̀ náà kò ràn ká ara aṣọ náà yálà aṣọ títa, aṣọ híhun tàbí aláwọ.
54
Kí ó pàṣẹ pé kí wọ́n fọ ohunkóhun tí ó bàjẹ́ náà kí ó sì wà ní ìpamọ́ fún ọjọ́ méje mìíràn.
55
Lẹ́yìn tí ẹ bá ti fọ ohun tí ẹ̀tẹ̀ náà mú tan, kí àlùfáà yẹ̀ ẹ́ wò, bí ẹ̀tẹ̀ náà kò bá yí àwọn aṣọ náà padà, bí kò tilẹ̀ tí ì ràn, àìmọ́ ni ó jẹ́. Ẹ fi iná sun un, yálà ẹ̀gbẹ́ kan tàbí òmíràn ni ẹ̀tẹ̀ náà dé.
56
Bí àlùfáà bá yẹ̀ ẹ́ wò ti ẹ̀tẹ̀ náà bá ti kúrò níbẹ̀, lẹ́yìn tí a ti fọ ohunkóhun tí ó mú, kí ó ya ibi tí ó bàjẹ́ kúrò lára aṣọ náà, awọ náà, aṣọ híhun náà tàbí aṣọ títa náà.
57
Ṣùgbọ́n bí ó bá tún ń farahàn níbi aṣọ náà, lára aṣọ títa náà, lára aṣọ híhun náà tàbí lára ohun èlò awọ náà, èyí fihàn pé ó ń ràn ká. Gbogbo ohun tí ẹ̀tẹ̀ náà bá wà lára rẹ̀ ni kí ẹ fi iná sun.
58
Aṣọ náà, aṣọ títa náà, aṣọ híhun náà tàbí ohun èlò awọ náà tí a ti fọ̀ tí ó sì mọ́ lọ́wọ́ ẹ̀tẹ̀ náà ni kí a tún fọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Yóò sì di mímọ́.”
59
Èyí ni òfin ààrùn, nínú aṣọ bubusu, ti aṣọ ọ̀gbọ̀, ti aṣọ títa, ti aṣọ híhun tàbí ti ohun èlò awọ, láti fihàn bóyá wọ́n wà ní mímọ́ tàbí àìmọ́.
Settings