Skip to content
Ẹkún Jeremiah 3:21-33

Ẹkún Jeremiah 3:21-33

21
Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn àti nítorí náà ní mo nírètí.
22
Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.
23
Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀.
24
Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.
25
Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a.
26
Ó dára kí a ní sùúrù fún ìgbàlà Olúwa.
27
Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà nígbà tí ó wà ní èwe.
28
Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí Olúwa ti fi fún un.
29
Jẹ́ kí ó bo ojú rẹ̀ sínú eruku— ìrètí sì lè wà.
30
Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a, sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.
31
Ènìyàn kò di ìtanù lọ́dọ̀ Olúwa títí láé.
32
Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn, nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.
33
Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options