Skip to content
Onidajọ 8:1-10

Onidajọ 8:1-10

1
Àwọn àgbàgbà ẹ̀yà Efraimu sì bínú gidigidi sí Gideoni wọ́n bi í léèrè pé, kí ló dé tí o fi ṣe irú èyí sí wa? Èéṣe tí ìwọ kò fi pè wá nígbà tí ìwọ kọ́kọ́ jáde lọ láti bá àwọn ará Midiani jagun? Ohùn ìbínú ni wọ́n fi bá a sọ̀rọ̀.
2
Ṣùgbọ́n Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Àṣeyọrí wo ni mo ti ṣe tí ó tó fiwé tiyín? Àṣàkù àjàrà Efraimu kò ha dára ju gbogbo ìkórè àjàrà Abieseri lọ bí?
3
Ọlọ́run ti fi Orebu àti Seebu àwọn olórí àwọn ará Midiani lé yín lọ́wọ́. Kí ni ohun tí Mose ṣe tí ó tó fiwé e yín tàbí tí ó tó àṣeyọrí i yín?” Nígbà tí ó wí èyí ríru ìbínú wọn rọlẹ̀.
4
Gideoni àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tẹ̀síwájú láti lépa àwọn ọ̀tá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ wọ́n, wọ́n dé Jordani wọ́n sì kọjá sí òdìkejì.
5
Ó wí fún àwọn ọkùnrin Sukkoti pé, “Ẹ fún àwọn ọmọ-ogun mi ní oúnjẹ díẹ̀, nítorí ó ti rẹ̀ wọ́n, èmi sì ń lépa Seba àti Salmunna àwọn ọba Midiani.”
6
Ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè Sukkoti fèsì pé ṣé ọwọ́ rẹ ti tẹ Seba àti Salmunna náà ni? Èéṣe tí àwa yóò ṣe fún àwọn ológun rẹ ní oúnjẹ?
7
Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Ó dára, nígbà tí Olúwa bá fi Seba àti Salmunna lé mi lọ́wọ́ tán èmi yóò fi ẹ̀gún ijù àti ẹ̀gún òṣùṣú ya ẹran-ara yín.”
8
Láti ibẹ̀, ó lọ sí Penieli ó sì bẹ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ṣùgbọ́n àwọn náà dá a lóhùn bí àwọn ará Sukkoti ti dá a lóhùn.
9
Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ọkùnrin Penieli pé, “Nígbà tí mo bá ṣẹ́gun tí mo sì padà dé ní àlàáfíà, èmi yóò wó ilé ìṣọ́ yìí.”
10
Ní àsìkò náà Seba àti Salmunna wà ní Karkori pẹ̀lú ọmọ-ogun wọn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) ọkùnrin, àwọn wọ̀nyí ni ó ṣẹ́kù nínú gbogbo ogun àwọn ènìyàn apá ìlà-oòrùn, nítorí ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) ọkùnrin tí ó fi idà jà ti kú ní ojú ogun.
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options