Onidajọ 3:1-7
1
Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa fi sílẹ̀ láti dán àwọn ìran tuntun ní Israẹli wò, àwọn ìran tí kò ì tí ì ní ìrírí ogun àwọn ará Kenaani.
2
(Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Israẹli tí kò rí ogun rí níbí a ti ṣe ń jagun).
3
Àwọn ìjòyè ìlú Filistini márààrún, gbogbo àwọn ará Kenaani, àwọn ará Sidoni, àti àwọn ará Hifi tí ń gbé ní àwọn òkè Lebanoni bẹ̀rẹ̀ láti òkè Baali-Hermoni títí dé Lebo-Hamati.
4
A fi àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láti dán àwọn Israẹli wò bóyá wọn yóò gbọ́rọ̀ sí àwọn òfin Olúwa, èyí tí ó ti fi fún àwọn baba wọn láti ipasẹ̀ Mose.
5
Àwọn ọmọ Israẹli gbé láàrín àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti àwọn ará Amori, àwọn ará Peresi, àwọn ará Hifi àti àwọn ará Jebusi.
6
Dípò kí wọ́n run àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Israẹli ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọbìnrin Israẹli fún àwọn ará ilẹ̀ náà ní aya, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn.
7
Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣe èyí tí ó burú níwájú Olúwa, wọ́n gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin Baali àti Aṣerah.
Settings