Skip to content
Onidajọ 13:15-23

Onidajọ 13:15-23

15
Manoa sọ fún angẹli Olúwa náà pé, “Jọ̀wọ́ dára dúró títí àwa yóò fi pèsè ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan fún ọ.”
16
Angẹli Olúwa náà dá Manoa lóhùn pé, “Bí ẹ̀yin tilẹ̀ dá mi dúró, èmi kì yóò jẹ ọ̀kankan nínú oúnjẹ tí ẹ̀yin yóò pèsè. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá fẹ́ ẹ pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, kí ẹ sì fi rú ẹbọ sí Olúwa.” (Manoa kò mọ̀ pé angẹli Olúwa ní i ṣe.)
17
Manoa sì béèrè lọ́wọ́ angẹli Olúwa náà pé, “Kí ni orúkọ rẹ, kí àwa bá à lè fi ọlá fún ọ nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ bá ṣẹ?”
18
Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa náà dáhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ ń béèrè orúkọ mi? Ìyanu ni, ó kọjá ìmọ̀.”
19
Lẹ́yìn náà ni Manoa mú ọ̀dọ́ ewúrẹ́, pẹ̀lú ẹbọ ọkà, ó sì fi rú ẹbọ lórí àpáta kan sí Olúwa. Nígbà tí Manoa àti ìyàwó dúró tí wọn ń wò Olúwa ṣe ohun ìyanu kan.
20
Bí ẹ̀là ahọ́n iná ti là jáde láti ibi pẹpẹ ìrúbọ náà sí ọ̀run, angẹli Olúwa gòkè re ọ̀run láàrín ahọ́n iná náà. Nígbà tí wọ́n rí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Manoa àti aya rẹ̀ wólẹ̀ wọ́n sì dojúbolẹ̀.
21
Nígbà tí angẹli Olúwa náà kò tún fi ara rẹ̀ han Manoa àti aya rẹ̀ mọ́, Manoa wá mọ̀ pé angẹli Olúwa ni.
22
Manoa sọ fún aya rẹ̀ pé, “Dájúdájú àwa yóò kú nítorí àwa ti fi ojú rí Ọlọ́run.”
23
Ṣùgbọ́n ìyàwó rẹ̀ dáhùn pé, “Bí Olúwa bá ní èrò àti pa wá kò bá tí gba ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wa, tàbí fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn wá tó sọ nǹkan ìyanu yìí fún wa.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options