Joṣua 9:7-15
7
Àwọn ọkùnrin Israẹli sọ fún àwọn ará Hifi pé, “Ṣùgbọ́n bóyá tòsí wa ni ẹ ń gbé. Báwo ni a ó ṣe lè ṣe àdéhùn pẹ̀lú yín?”
8
“Ìránṣẹ́ rẹ ní àwa í ṣe.” Wọ́n sọ fún Joṣua. Ṣùgbọ́n Joṣua béèrè, “Ta ni yín àti pé níbo ni ẹ̀yin ti wá?”
9
Wọ́n sì dáhùn pé, “Ní ilẹ̀ òkèèrè ní àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wá, nítorí orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nítorí tí àwa ti gbọ́ òkìkí rẹ àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe ní Ejibiti,
10
àti ohun gbogbo tí ó ti ṣe sí ọba àwọn Amori méjèèje tí ń bẹ ní òkè Jordani, sí Sihoni ọba Heṣboni, àti Ogu ọba Baṣani, tí wọ́n jẹ ọba ní Aṣtarotu.
11
Àwọn àgbàgbà wa àti gbogbo àwọn tí ń gbé ìlú wa sọ fún wa pé, ‘Ẹ mú oúnjẹ lọ́wọ́ fún ìrìnàjò yín, ẹ lọ pàdé wọn, kí ẹ sì sọ fún wọn pé, “Àwa ni ìránṣẹ́ yín, ẹ dá àdéhùn pẹ̀lú wa.” ’
12
Gbígbóná ní a mú oúnjẹ wa wá, nígbà tí a dì í ní ilé ní ọjọ́ tí à ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín. Ṣùgbọ́n ẹ wò ó bí ó ṣe gbẹ àti bí ó sì ṣe bu nísinsin yìí.
13
Àti ìgò wáìnì wọ̀nyí, tí àwa rọ kún tuntun ni, ṣùgbọ́n ẹ wò ó bí wọ́n ti sán. Aṣọ àti bàtà wa ni ó sì ti gbó nítorí ìrìnàjò ọ̀nà jíjìn.”
14
Àwọn ọkùnrin Israẹli sì yẹ oúnjẹ wọn wò, wọn kò sì wádìí ní ọwọ́ Olúwa.
15
Nígbà náà ni Joṣua ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú wọn láti dá wọn sí, àti àwọn olórí ìjọ ènìyàn fi ọwọ́ sí àdéhùn náà nípa ṣíṣe ìbúra.
Settings