Skip to content
Joṣua 15:1-12

Joṣua 15:1-12

1
Ìpín fún ẹ̀yà Juda, ní agbo ilé agbo ilé, títí dé agbègbè Edomu, títí dé aginjù Sini ní òpin ìhà gúúsù.
2
Ààlà wọn ní ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ láti etí òpin ìhà gúúsù Òkun Iyọ̀,
3
ó sì gba gúúsù Akrabbimu lọ, títí dé Sini àti sí iwájú ìhà gúúsù Kadeṣi-Barnea. Nígbà náà ó sì tún kọjá Hesroni lọ sí Adari, ó sì tún yípo yíká lọ sí Karka.
4
Ó tún kọjá lọ sí Asmoni, ó sì papọ̀ mọ́ Wadi ti Ejibiti, ó parí sí Òkun. Èyí ni ààlà wọn ní ìhà gúúsù.
5
Ààlà wọn ní ìhà ìlà-oòrùn ní Òkun Iyọ̀ títí dé ẹnu Jordani. Ààlà àríwá bẹ̀rẹ̀ láti etí òkun ní ẹnu Jordani,
6
ààlà náà sì tún dé Beti-Hogla, ó sì lọ sí ìhà àríwá Beti-Araba. Ààlà náà sì tún dé ibi Òkúta Bohani ti ọmọ Reubeni.
7
Ààlà náà gòkè lọ títí dé Debiri láti àfonífojì Akori, ó sì yípadà sí àríwá Gilgali, èyí tí ń bẹ ní iwájú òkè Adummimu, tí ń bẹ ní ìhà gúúsù odò náà. Ó sì tẹ̀síwájú sí apá omi En-Ṣemeṣi, ó sì jáde sí En-Rogeli.
8
Ààlà náà sì tún gòkè lọ sí àfonífojì Beni-Hinnomu ní ìhà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ gúúsù ti Jebusi (tí í ṣe Jerusalẹmu). Ó sì gòkè lọ sí orí òkè tí ó wà lórí àfonífojì Hinnomu tí ń bẹ ní ìpẹ̀kun àfonífojì Refaimu ní ìhà àríwá.
9
Ààlà náà sì lọ láti orí òkè lọ sí ìsun omi Nefitoa, ó sì jáde sí ìlú òkè Efroni, ó sì lọ sí apá ìsàlẹ̀ Baalahi (tí í ṣe, Kiriati-Jearimu).
10
Ààlà tí ó yípo láti Baalahi lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn sí òkè Seiri, ó sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Jearimu (tí í ṣe, Kesaloni), ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Beti-Ṣemeṣi, ó sì kọjá lọ sí Timna.
11
Ààlà náà sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Ekroni, ó sì yípadà lọ sí Ṣikkeroni, ó sì yípadà lọ sí òkè Baalahi, ó sì dé Jabneeli, ààlà náà sì parí sí Òkun.
12
Ààlà ìwọ̀-oòrùn sì jẹ́ agbègbè Òkun Ńlá. Ìwọ̀nyí ni ààlà àyíká ènìyàn Juda ní agbo ilé wọn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options