Joṣua 12:7-24
7
Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jordani, láti Baali-Gadi ní àfonífojì Lebanoni sí òkè Halaki, èyí tí o lọ sí ọ̀nà Seiri (Joṣua sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Israẹli ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn:
8
ilẹ̀ òkè, ní ẹsẹ̀ òkè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn òkè aginjù, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní aginjù àti nì gúúsù ilẹ̀ àwọn ará: Hiti, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti àwọn ará Jebusi).
9
Ọba Jeriko, ọ̀kan ọba Ai (tí ó wà nítòsí Beteli), ọ̀kan
10
ọba Jerusalẹmu, ọ̀kan ọba Hebroni, ọ̀kan
11
ọba Jarmatu, ọ̀kan ọba Lakiṣi, ọ̀kan
12
ọba Egloni, ọ̀kan ọba Geseri, ọ̀kan
13
ọba Debiri, ọ̀kan ọba Gederi, ọ̀kan
14
ọba Horma, ọ̀kan ọba Aradi, ọ̀kan
15
ọba Libina, ọ̀kan ọba Adullamu, ọ̀kan
16
ọba Makkeda, ọ̀kan ọba Beteli, ọ̀kan
17
ọba Tapua, ọ̀kan ọba Heferi, ọ̀kan
18
ọba Afeki, ọ̀kan ọba Laṣaroni, ọ̀kan
19
ọba Madoni, ọ̀kan ọba Hasori, ọ̀kan
20
ọba Ṣimroni-Meroni, ọ̀kan ọba Akṣafu, ọ̀kan
21
ọba Taanaki, ọ̀kan ọba Megido, ọ̀kan
22
ọba Kedeṣi, ọ̀kan ọba Jokneamu ni Karmeli, ọ̀kan
23
ọba Dori (ní Nafoti Dori), ọ̀kan ọba Goyimu ní Gilgali, ọ̀kan
24
ọba Tirsa, ọ̀kan. Gbogbo àwọn ọba náà jẹ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n.
Settings