Skip to content
Joẹli 2:1-8

Joẹli 2:1-8

1
Ẹ fun ìpè ní Sioni, ẹ sì fún ìpè ìdágìrì ní òkè mímọ́ mi. Jẹ́ kí àwọn ará ilẹ̀ náà wárìrì, nítorí tí ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá, nítorí ó kù sí dẹ̀dẹ̀.
2
Ọjọ́ òkùnkùn àti ìrọ́kẹ̀kẹ̀, ọjọ́ ìkùùkuu àti òkùnkùn biribiri. Bí ọyẹ́ òwúrọ̀ ti í la bo orí àwọn òkè ńlá: àwọn ènìyàn ńlá àti alágbára; ya dé, ti kó ti ì sí irú rẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni irú rẹ̀ kì yóò sí mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, títí dé ọdún ìran dé ìran.
3
Iná ń jó níwájú wọ́n; ọwọ́ iná sì ń jó lẹ́yìn wọn. Ilẹ̀ náà dàbí ọgbà Edeni níwájú wọn, àti lẹ́yìn wọn bí ahoro ijù; nítòótọ́, kò sì sí ohun tí yóò bọ́ lọ́wọ́ wọn.
4
Ìrí wọn dàbí ìrí àwọn ẹṣin; wọ́n ń sáré lọ bí àwọn ẹlẹ́ṣin ogun.
5
Bí ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ni wọn ń fo ní orí òkè bí ariwo ọ̀wọ́-iná tí ń jó koríko gbígbẹ, bí akọni ènìyàn tí a kójọ fún ogun.
6
Ní ojú wọn, àwọn ènìyàn yóò jẹ ìrora púpọ̀: gbogbo ojú ní yóò ṣú dudu.
7
Wọn yóò sáré bi àwọn alágbára; wọn yóò gùn odi bí ọkùnrin ológun; olúkúlùkù wọn yóò sì rìn lọ ní ọ̀nà rẹ̀, wọn kì yóò sì yà kúrò ni ọ̀nà wọn.
8
Bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò kọlu ẹnìkejì rẹ̀; olúkúlùkù wọn yóò rìn ní ọ̀nà rẹ̀, nígbà tí wọn bá sì ṣubú lù idà wọn kì yóò gbọgbẹ́.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 90 chars

Options