मुख्य सामग्री पर जाएँ
Jobu 34:16-30

Ìṣàkóso aláìṣojúsàájú àti ìdájọ́ Ọlọ́run

Jobu 34:16-30
16
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, bí ìwọ bá ní òye, gbọ́ èyí; fetísí ohùn ẹnu mi.
17
Ẹni tí ó kórìíra òtítọ́ ha le ṣe olórí bí? Ìwọ ó ha sì dá olóòótọ́ àti ẹni ńlá lẹ́bi?
18
O ha tọ́ láti wí fún ọba pé, ‘Ènìyàn búburú ní ìwọ,’ tàbí fún àwọn ọmọ-aládé pé, ‘Ìkà ni ẹ̀yin,’
19
mélòó mélòó fún ẹni tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn ọmọ-aládé tàbí tí kò kà ọlọ́rọ̀ sí ju tálákà lọ, nítorí pé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn í ṣe?
20
Ní ìṣẹ́jú kan ni wọn ó kú, àwọn ènìyàn á sì di yíyọ́ lẹ́nu láàrín ọ̀gànjọ́, wọn a sì kọjá lọ; a sì mú àwọn alágbára kúrò láìsí ọwọ́ ènìyàn níbẹ̀.
21
“Nítorí pé ojú rẹ̀ ń bẹ ní ipa ọ̀nà ènìyàn, òun sì rí ìrìn rẹ̀ gbogbo.
22
Kò sí ibi òkùnkùn, tàbí òjìji ikú, níbi tí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ yóò gbé sá pamọ́ sí.
23
Nítorí pé òun kò pẹ́ àti kíyèsi ẹnìkan, kí òun kí ó sì mú lọ sínú ìdájọ́ níwájú Ọlọ́run.
24
Òun ó sì fọ́ àwọn alágbára túútúú láìní ìwádìí, a sì fi ẹlòmíràn dípò wọn,
25
nítorí pé ó mọ iṣẹ́ wọn, ó sì yí wọn po ní òru, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
26
Ó kọlù wọ́n nítorí ìwà búburú wọn níbi tí àwọn ẹlòmíràn ti lè rí i,
27
nítorí pé wọ́n padà pẹ̀yìndà sí i, wọn kò sì fiyèsí ipa ọ̀nà rẹ̀ gbogbo,
28
kí wọn kí ó sì mú igbe ẹkún àwọn tálákà lọ dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, òun sì gbọ́ igbe ẹkún aláìní.
29
Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dákẹ́ síbẹ̀, ta ni yóò dá lẹ́bi? Nígbà tí ó bá pa ojú rẹ̀ mọ́, ta ni yóò lè rí i? Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe si orílẹ̀-èdè tàbí sí ènìyàn kan ṣoṣo;
30
kí aláìwà bi Ọlọ́run kí ó má bá à jẹ ọba kí wọn kí ó má di ìdẹwò fún ènìyàn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options