Jobu 20:12-21
12
“Bí ìwà búburú tilẹ̀ dún ní ẹnu rẹ̀, bí ó tilẹ̀ pa á mọ́ nísàlẹ̀ ahọ́n rẹ̀,
13
bí ó tilẹ̀ dá a sì, tí kò si kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ó pa á mọ́ síbẹ̀ ní ẹnu rẹ̀,
14
ṣùgbọ́n oúnjẹ rẹ̀ nínú ikùn rẹ̀ ti yípadà, ó jásí òróró paramọ́lẹ̀ nínú rẹ̀;
15
Ó ti gbé ọrọ̀ mì, yóò sì tún bí i jáde; Ọlọ́run yóò pọ̀ ọ́ yọ jáde láti inú rẹ̀ wá.
16
Ó ti fà oró paramọ́lẹ̀ mú; ahọ́n ejò olóró ní yóò pa á.
17
Kì yóò rí odò wọ̀n-ọn-nì, ìṣàn omi, odò tí ń ṣàn fún oyin àti ti òrí-àmọ́.
18
Ohun tí ó ṣiṣẹ́ fún ni yóò mú un padà, kí yóò sì gbé e mì; gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ tí ó ní, kì yóò sì ìgbádùn nínú rẹ̀.
19
Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni tálákà lára, ó sì ti pẹ̀yìndà si wọ́n; nítorí ti ó fi agbára gbé ilé tí òun kò kọ́.
20
“Nítorí òun kò mọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ nínú ara rẹ̀, kì yóò sì gbà nínú èyí tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ sílẹ̀.
21
Ohun kan kò kù fún jíjẹ́ rẹ̀; nítorí náà ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì yóò dúró pẹ́.
Settings