Jobu 1:1-5
1
Ọkùnrin kan wà ní ilẹ̀ Usi, orúkọ ẹni tí í jẹ́ Jobu; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́, ó dúró ṣinṣin, ẹni tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó kórìíra ìwà búburú.
2
A sì bi ọmọkùnrin méje àti ọmọbìnrin mẹ́ta fún un.
3
Ohun ọ̀sìn rẹ̀ sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ìbákasẹ, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) àjàgà ọ̀dá màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (500) abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì pọ̀; bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin yìí sì pọ̀jù gbogbo àwọn ará ìlà-oòrùn lọ.
4
Àwọn ọmọ rẹ̀ a sì máa lọ í jẹun àsè nínú ilé ara wọn, olúkúlùkù ní ọjọ́ rẹ̀; wọn a sì máa ránṣẹ́ pé arábìnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láti jẹun àti láti pẹ̀lú wọn.
5
Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ àsè wọn pé yíká, ni Jobu ránṣẹ́ lọ í yà wọ́n sí mímọ́, ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì rú ẹbọ sísun níwọ̀n iye gbogbo wọn; nítorí tí Jobu wí pé: bóyá àwọn ọmọ mi ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣọpẹ́ fún Ọlọ́run lọ́kàn wọn. Bẹ́ẹ̀ ní Jobu máa ń ṣe nígbà gbogbo.
Settings