Jeremiah 6:10-15
10
Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn? Ta ni yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi? Etí wọn ti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́. Ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ ohun búburú sí wọn, wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀.
11
Èmi kún fún ìbínú Olúwa, èmi kò sì le è pa á mọ́ra. “Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro, àti sórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kó ra wọn jọ pọ̀, àti ọkọ àti aya ni a ò mú sínú rẹ̀, àti àwọn arúgbó tí ó ní ọjọ́ kíkún lórí.
12
Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn, oko wọn àti àwọn aya wọn, nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,” ni Olúwa wí.
13
“Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí ẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọn ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè, àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀ sì kún fún ẹ̀tàn.
14
Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi bí ẹni pé kò tó nǹkan. Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà,’ nígbà tí kò sì sí àlàáfíà.
15
Ojú ha a tì wọ́n nítorí ìwà ìríra wọn bí? Rárá, wọn kò ní ìtìjú mọ́, wọn kò tilẹ̀ ní oorun ìtìjú. Nítorí náà, wọn ó ṣubú láàrín àwọn tó ṣubú, a ó sì ké wọn lulẹ̀ nígbà tí mo bá bẹ̀ wọ́n wò,” ni Olúwa wí.
Settings