Jeremiah 42:15-18
15
nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ìyókù Juda èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: ‘Bí ẹ̀yin bá pinnu láti lọ sí Ejibiti láti lọ ṣe àtìpó níbẹ̀.
16
Yóò sì ṣe, idà tí ẹ̀yin bẹ̀rù yóò sì lé e yín bá níbẹ̀; àti ìyanu náà tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù yóò sì tẹ̀lé yín lọ sí Ejibiti àti pé ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò kú sí.
17
Nítorí náà, gbogbo àwọn tí ó ti pinnu láti ṣe àtìpó ní Ejibiti ni yóò ti ipa idà kú, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn kò sì ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú wọn yè tàbí sá àsálà nínú ibi tí èmi yóò mú wá sórí wọn.’
18
Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí èmi ti da ìbínú àti ìrunú síta sórí àwọn tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni ìrunú mi yóò dà síta sórí yín, nígbà tí ẹ̀yin bá lọ sí Ejibiti. Ẹ̀yin ó sì di ẹni ègún àti ẹni ẹ̀gàn àti ẹ̀sín, ẹ̀yin kì yóò sì rí ibí yìí mọ́.’
Settings