Ugrás a tartalomhoz
Jeremiah 31:1-9

Jeremiah 31:1-9

1
“Nígbà náà, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run fún gbogbo ìdílé ìran Israẹli, àwọn náà yóò sì jẹ́ ènìyàn mi,” ni Olúwa wí.
2
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Àwọn ènìyàn tí ó sá àsálà lọ́wọ́ idà yóò rí ojúrere Olúwa ní aṣálẹ̀, Èmi yóò sì fi ìsinmi fún Israẹli.”
3
Olúwa ti fi ara rẹ̀ hàn wá ní ìgbà kan rí, ó wí pé: “Èmi ti nífẹ̀ẹ́ yín pẹ̀lú ìfẹ́ àìlópin; mo ti fi ìfẹ́ ńlá fà yín,
4
Èmi yóò tún gbé e yín sókè, àní a ó tún gbé e yín ró ìwọ wúńdíá ilẹ̀ Israẹli. Àní ẹ ó tún tún ohun èlò orin yín gbé, ẹ ó sì jáde síta pẹ̀lú ijó àti ayọ̀.
5
Ẹ ó tún gbin ọgbà àjàrà ní orí òkè Samaria; àwọn àgbẹ̀ yóò sì máa gbádùn èso oko wọn.
6
Ọjọ́ kan máa wà tí àwọn olùṣọ́ yóò kígbe jáde lórí òkè Efraimu wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ sí Sioni, ní ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wa.’ ”
7
Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ wí pé: “Ẹ fi ayọ̀ kọrin sí Jakọbu; ẹ hó sí olórí àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo. Jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ìyìn rẹ kí o sì wí pé, ‘Olúwa, gba àwọn ènìyàn rẹ là; àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli.’
8
Wò ó, Èmi yóò mú wọn wá láti ilẹ̀ àríwá; èmi yóò kó gbogbo wọn jọ láti òpin ayé. Lára wọn ni yóò jẹ́ afọ́jú àti arọ, aboyún àti obìnrin tí ń rọbí, ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wá.
9
Wọn yóò wá pẹ̀lú ẹkún, wọn yóò gbàdúrà bí Èmi yóò ṣe mú wọn padà. Èmi yóò jẹ́ atọ́nà fún wọn ní ẹ̀bá odò omi; ní ọ̀nà tí ó tẹ́jú tí wọn kì yóò le ṣubú, nítorí èmi ni baba Israẹli, Efraimu sì ni àkọ́bí ọkùnrin mi.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options