Skip to content
Jeremiah 3:12-22

Jeremiah 3:12-22

12
Lọ polongo ọ̀rọ̀ náà, lọ sí ìhà àríwá: “ ‘Yípadà, Israẹli aláìnígbàgbọ́,’ ni Olúwa wí. ‘Ojú mi kì yóò korò sí ọ mọ́, nítorí mo jẹ́ aláàánú, ni Olúwa wí. Èmi kì yóò sì bínú mọ́ títí láé.
13
Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ, ìwọ ti ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ, ìwọ ti wá ojúrere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì lábẹ́ gbogbo igikígi tí ó gbilẹ̀, ẹ̀yin kò gba ohun mi gbọ́,’ ” ni Olúwa wí.
14
“Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni Olúwa wí, “nítorí èmi ni ọkọ rẹ. Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà. Èmi ó sì mú ọ wá sí Sioni.
15
Lẹ́yìn èyí, èmi ó fún ọ ní àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti inú ọkàn mi, tí wọn yóò ṣáájú yín pẹ̀lú òye àti ìmọ̀.
16
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí ẹ̀yin bá pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ náà,” ni Olúwa wí, “àwọn ènìyàn kò tún lè sọ pé, ‘Àpótí ẹ̀rí Olúwa.’ Kò ní wá sí ìrántí wọn mọ́, a kì yóò pàdánù rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sì tún kan òmíràn mọ́.
17
Ní ìgbà náà, wọn yóò pe Jerusalẹmu ní ìtẹ́ Olúwa gbogbo orílẹ̀-èdè yóò péjọ sí Jerusalẹmu láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ Olúwa, wọn kì yóò sì tún tẹ̀lé àyà líle búburú wọn mọ́.
18
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ni ilé Juda yóò darapọ̀ mọ́ ilé Israẹli. Wọn yóò sì wá láti ilẹ̀ àríwá wá sí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní.
19
“Èmi fúnra mi sọ wí pé, “ ‘Báwo ni inú mi yóò ti dùn tó, kí èmi kí ó tọ́ ọ bí ọmọkùnrin kí n sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó tó.’ Mo rò pé ìwọ yóò pè mí ní ‘Baba mi’ o kò sì ní ṣàì tọ̀ mí lẹ́yìn.
20
Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí aláìgbàgbọ́ obìnrin sí ọkọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ o jẹ́ aláìgbàgbọ́ sí mi. Ìwọ ilé Israẹli,” ni Olúwa wí.
21
A gbọ́ ohùn àgàn láti ibi gíga, ẹkún àti ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, nítorí wọ́n ti yí ọ̀nà wọn po, wọ́n sì ti gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn.
22
“Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́, Èmi ó wo ìpadàsẹ́yìn kúrò ní ọ̀nà títọ́ rẹ sàn.” “Bẹ́ẹ̀, ni a ó wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run wa.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options