Jeremiah 16:1-9
1
Bákan náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
2
“Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ìyàwó, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin níbí yìí.”
3
Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí nípa ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin tí wọ́n bá bí nílẹ̀ yìí, àti ìyá tí ó bí wọn àti baba wọn.
4
“Wọn yóò kú ikú ààrùn, wọn kò ní sin wọ́n tàbí ṣọ̀fọ̀ fún wọn. Wọn ó dàbí ìdọ̀tí lórí ilẹ̀; wọn ó ṣègbé pẹ̀lú idà àti ìyàn. Òkú wọn yóò sì di oúnjẹ fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.”
5
Nítorí báyìí ni Olúwa wí: “Má ṣe wọ ilé tí oúnjẹ ìsìnkú wà, má ṣe lọ síbẹ̀ láti káàánú tàbí ṣọ̀fọ̀, nítorí mo ti mú àlàáfíà, ìfẹ́ àti àánú mi kúrò lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,” ni Olúwa wí.
6
“Àti ẹni ńlá àti kékeré ni yóò ṣègbé ní ilẹ̀ yìí, wọn kò ní sin wọ́n tàbí ṣọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí yóò fá irun orí wọn nítorí wọn.
7
Kò sí ẹni tí yóò fi oúnjẹ tu àwọn tí í ṣọ̀fọ̀ nínú, kódà kì í ṣe fún baba tàbí fún ìyá, kì yóò sí ẹni tí yóò fi ohun mímu tù wọ́n nínú.
8
“Ìwọ kò gbọdọ̀ lọ sí ilé tí àjọyọ̀ wà, má ṣe jókòó jẹun tàbí mu ohun mímu.
9
Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli wí, Ní ojú yín ní ọjọ́ yín ni òpin yóò dé bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú, àti sí ohùn ìyàwó àti ọkọ ìyàwó ní ibí yìí.
Settings