Isaiah 64:5-12
5
Ìwọ a máa wá fún ìrànlọ́wọ́ àwọn tí wọn ń fi ayọ̀ ṣe ohun tó tọ́, tí ó rántí ọ̀nà rẹ. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bẹ̀rẹ̀ sí dẹ́ṣẹ̀ sí wọn, inú bí ọ. Báwo ni a ó ṣe gbà wá là?
6
Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́, gbogbo òdodo wa sì dàbí èkísà ẹlẹ́gbin; gbogbo wa kákò bí ewé, àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò.
7
Ẹnikẹ́ni kò pe orúkọ rẹ tàbí kí ó gbìyànjú láti dì ẹ́ mú; nítorí ìwọ ti fi ojú rẹ pamọ́ fún wa ó sì jẹ́ kí àwa ṣòfò dànù nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.
8
Síbẹ̀síbẹ̀, Olúwa, ìwọ ni Baba wa. Àwa ni amọ̀, ìwọ ni amọ̀kòkò; gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
9
Má ṣe bínú kọjá ààlà, ìwọ Olúwa, má ṣe rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa títí láé. Jọ̀wọ́, bojú wò wá, ni a gbàdúrà, nítorí ènìyàn rẹ ni gbogbo wa.
10
Àwọn ìlú mímọ́ rẹ ti di aṣálẹ̀; Sioni pàápàá di aṣálẹ̀, Jerusalẹmu di ahoro.
11
Tẹmpili mímọ́ ológo wa, níbi tí àwọn baba wa ti yìn ọ́, ni a ti fi iná sun, àti ohun gbogbo tí í ṣe ìṣúra wa ti dahoro.
12
Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí, Olúwa, ìwọ ó ha sì tún fi ara rẹ pamọ́ bí? Ìwọ ó ha dákẹ́ kí o sì fìyà jẹ wá kọjá ààlà bí?
Settings