Skip to content
Isaiah 44:24-28

Isaiah 44:24-28

24
“Ohun tí Olúwa wí nìyìí Olùràpadà rẹ tí ó mọ ọ́ láti inú ìyá rẹ wá: “Èmi ni Olúwa tí ó ti ṣe ohun gbogbo tí òun nìkan ti na àwọn ọ̀run tí o sì tẹ́ ayé pẹrẹsẹ òun tìkára rẹ̀,
25
ta ni ó ba àmì àwọn wòlíì èké jẹ́ tí ó sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀, tí ó dojú ìmọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n délẹ̀ tí ó sì sọ wọ́n di òmùgọ̀,
26
ẹni tí ó gbé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde tí ó sì mú àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìmúṣẹ, “ẹni tí ó wí nípa ti Jerusalẹmu pé, ‘A ó máa gbé inú rẹ̀,’ àti ní ti àwọn ìlú Juda, ‘A ó tún kọ́,’ àti àwọn ahoro rẹ̀, ‘Èmi yóò mú un bọ̀ sípò,’
27
ta ni ó sọ fún omi jíjìn pé, ‘Ìwọ gbẹ, èmi yóò sì mú omi odò rẹ gbẹ,’
28
ta ni ó sọ nípa Kirusi pé, ‘Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn mi àti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́; òun yóò sọ nípa Jerusalẹmu pé, “Jẹ́ kí a tún kọ́,” àti nípa tẹmpili, “Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀.” ’ ”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options