Isaiah 43:1-7
1
Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìí, ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu, ẹni tí ó mọ ọ́, ìwọ Israẹli: “Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè; Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe.
2
Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá, Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ; àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá, kò ní jó ọ; ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.
3
Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ; Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ, Kuṣi àti Seba dípò rẹ.
4
Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi, àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ, Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ, àti ènìyàn dípò ẹ̀mí rẹ.
5
Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ; Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà-oòrùn wá èmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀-oòrùn.
6
Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’ Àti fún gúúsù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’ Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jíjìn wá àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—
7
ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́, tí mo dá fún ògo mi, tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”
Settings