Isaiah 37:15-20
15
Hesekiah sì gbàdúrà sí Olúwa:
16
Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli, tí ó gúnwà láàrín àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí i gbogbo ìjọba orílẹ̀ ayé. Ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé.
17
Tẹ́tí sílẹ̀, ìwọ Olúwa, kí o gbọ́, ya ojú rẹ, Ìwọ Olúwa, kí o rí i; tẹ́tí sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí Sennakeribu rán láti fi àbùkù kan Ọlọ́run alààyè.
18
“Òtítọ́ ni Olúwa pé àwọn ọba Asiria ti sọ àwọn ènìyàn àti ilẹ̀ wọn di asán.
19
Wọ́n ti da àwọn òrìṣà wọn sínú iná wọ́n sì ti pa wọ́n run, nítorí àwọn wọ̀nyí kì í ṣe ọlọ́run bí kò ṣe igi àti òkúta lásán, tí a ti ọwọ́ ènìyàn ṣe.
20
Nísinsin yìí, ìwọ Olúwa, Ọlọ́run wa, gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé yóò fi mọ̀ pé Ìwọ, Ìwọ nìkan, Olúwa ni Ọlọ́run.”
Settings