Isaiah 15:1-4
1
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Moabu, a pa Ari run ní Moabu, òru kan ní a pa á run! A pa Kiri run ní Moabu, òru kan ní a pa á run!
2
Diboni gòkè lọ sí tẹmpili rẹ̀, sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti sọkún, Moabu pohùnréré lórí Nebo àti Medeba. Gbogbo orí ni a fá gbogbo irùngbọ̀n ni a gé dànù.
3
Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà, ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede ìlú. Wọ́n pohùnréré, wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.
4
Heṣboni àti Eleale ké sóde, ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi. Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbe tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.
Settings