Skip to content
Hagai 2:2-10

Hagai 2:2-10

2
“Sọ fún Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, baálẹ̀ Juda, àti Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn yòókù. Béèrè lọ́wọ́ wọn pé,
3
‘Ta ni nínú yín tí ó kù tí ó sì ti rí ilé yìí ní ògo rẹ̀ àkọ́kọ́? Báwo ni ó ṣe ri sí yín nísinsin yìí? Ǹjẹ́ kò dàbí asán lójú yín?
4
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, múra gírí, ìwọ Serubbabeli,’ ni Olúwa wí. ‘Múra gírí, ìwọ Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. Ẹ sì múra gírí gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ náà,’ ni Olúwa wí, ‘kí ẹ sì ṣiṣẹ́. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
5
‘Èyí ni ohun tí Èmi fi bá a yín dá májẹ̀mú nígbà tí ẹ jáde kúrò ní Ejibiti, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí ì mi sì wà pẹ̀lú yín. Ẹ má ṣe bẹ̀rù.’
6
“Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Láìpẹ́ jọjọ, Èmi yóò mi àwọn ọrun àti ayé, Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.
7
Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fà sí tẹmpili yìí, Èmi yóò sì kún ilé yìí pẹ̀lú ògo,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
8
‘Tèmi ni fàdákà àti wúrà,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
9
‘Ògo ìkẹyìn ilé yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Àti ní ìhín yìí ni Èmi ó sì fi àlàáfíà fún ni,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
10
Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Hagai wá pé,
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options