Skip to content
Hagai 2:15-19

Hagai 2:15-19

15
“ ‘Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ ro èyí dáradára láti òní yìí lọ, ẹ kíyèsi bí nǹkan ṣe rí tẹ́lẹ̀, a to òkúta kan lé orí èkejì ní tẹmpili Olúwa.
16
Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi òkìtì òsùwọ̀n ogun, mẹ́wàá péré ni yóò ba níbẹ̀. Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá dé ibi ìfúntí wáìnì láti wọn àádọ́ta ìwọ̀n, ogún péré ni yóò ba níbẹ̀.
17
Mo fi ìrẹ̀dànù, ìmúwòdù àti yìnyín bá gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín jẹ; síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí ọ̀dọ̀ mi,’ ni Olúwa wí.
18
‘Láti òní lọ, láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán yìí kí ẹ kíyèsi, kí ẹ sì rò ó dáradára, ọjọ́ ti a fi ìpìlẹ̀ tẹmpili Olúwa lélẹ̀, rò ó dáradára.
19
Ǹjẹ́ èso ha wà nínú abà bí? Títí di àkókò yìí, àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pomegiranate, àti igi olifi kò ì tí ì so èso kankan. “ ‘Láti òní lọ ni èmi yóò bùkún fún un yin.’ ”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options