Skip to content
Hagai 2:20-23

Serubbábélì: Àpótí èdìdì tí Ọlọ́run yàn

Hagai 2:20-23

Serubbábélì: Àpótí èdìdì tí Ọlọ́run yàn

20
Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ Hagai wá nígbà kejì, ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù náà pé,
21
“Sọ fún Serubbabeli baálẹ̀ Juda pé èmi yóò mi àwọn ọ̀run àti ayé.
22
Èmi yóò bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, Èmi yóò sì pa agbára àwọn aláìkọlà run, Èmi yóò sì dojú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun dé, àti àwọn tí ń gùn wọ́n; ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin yóò ṣubú; olúkúlùkù nípa idà arákùnrin rẹ̀.”
23
Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Ní ọjọ́ náà, ìwọ ìránṣẹ́ mi Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Èmi yóò mú ọ, Èmi yóò sì sọ ọ di bí òrùka èdìdì mi, nítorí mo ti yan ọ, ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”

Study this passage

Commentary written on this passage, not on a single verse.

Where else Scripture says this.

  • Isaiah 43:10

    “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí, “Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn, tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà mí gbọ́ tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà. Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá, tàbí a ó wa rí òmíràn lẹ́yìn mi.
    from verse 23
  • Isaiah 42:1

    “Ìránṣẹ́ mi nìyìí, ẹni tí mo gbéró, àyànfẹ́ mi nínú ẹni tí mo láyọ̀; Èmi yóò fi Ẹ̀mí mi sínú rẹ̀ òun yóò sì mú ìdájọ́ wá sórí àwọn orílẹ̀-èdè.
    from verse 23
  • Jeremiah 22:24

    “Dájúdájú bí èmi ti wà láààyè,” ni Olúwa wí, “Bí Koniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda tilẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì lọ́wọ́ ọ̀tún mi, síbẹ̀ èmi ó fà ọ́ tu kúrò níbẹ̀.
    from verse 23
  • Orin Solomoni 8:6

    Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì bí èdìdì lé apá rẹ; nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú, ìjowú sì le bí isà òkú jíjò rẹ̀ rí bí jíjò iná, gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́-iná Olúwa.
    from verse 23
  • Sekariah 4:6

    Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Serubbabeli tó wí pé: ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò ṣe nípa Ẹ̀mí mi,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
    from verse 21
  • Mika 5:10

    “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Èmi yóò pa àwọn ẹṣin rẹ̀ run kúrò láàrín rẹ èmi yóò sì pa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ run.
    from verse 22
  • 1 Peteru 2:4

    Ẹni tí ẹ̀yin ń tọ̀ bọ̀, sí bi òkúta ààyè náà, èyí ti a ti ọwọ́ ènìyàn kọ̀ sílẹ̀ nítòótọ́, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àṣàyàn òkúta iyebíye.
    from verse 23
  • Sekariah 4:14

    Ó sì wí pé, “Àwọn méjì wọ̀nyí ni àwọn tí a fi òróró yàn, tí ó dúró ti Olúwa gbogbo ayé.”
    from verse 23
  • Hagai 2:6

    “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Láìpẹ́ jọjọ, Èmi yóò mi àwọn ọrun àti ayé, Òkun àti ìyàngbẹ ilẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.
    from verse 21
  • Hagai 2:7

    Èmi yóò mi gbogbo orílẹ̀-èdè, ìfẹ́ gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fà sí tẹmpili yìí, Èmi yóò sì kún ilé yìí pẹ̀lú ògo,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
    from verse 21
  • Sekariah 4:10

    “Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré? Nítorí wọn ó yọ̀ nígbà ti wọ́n bá rí okùn ìwọ̀n nì lọ́wọ́ Serubbabeli. “(Àwọn méje wọ̀nyí ni àwọn ojú Olúwa, tí ó ń sáré síyìn-ín sọ́hùn-ún ní gbogbo ayé.)”
    from verse 21
  • Onidajọ 7:22

    Nígbà tí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì fun fèrè wọn, Olúwa sì yí ojú idà ọkùnrin kọ̀ọ̀kan padà sí ẹnìkejì rẹ̀ àti sí gbogbo ogun wọn. Àwọn ọmọ-ogun sì sá títí dé Beti-Sitta ní ọ̀nà Serera títí lọ dé ìpínlẹ̀ Abeli-Mehola ní ẹ̀bá Tabbati.
    from verse 22
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options