Ẹ̀dùn ọkàn kejì Hábákúkù
12
Olúwa, ǹjẹ́ láti ayérayé kọ ni ìwọ tí wà? Olúwa Ọlọ́run mi. Ẹni mímọ́ mi, àwa kì yóò kú Olúwa, ìwọ tí yàn wọn fún ìdájọ́; Ọlọ́run alágbára, ìwọ tí fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ fún ìbáwí.
13
Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi; ìwọ kò le gbà ìwà ìkà nítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láààyè? Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń pa ẹni tí i ṣe olódodo ju wọn lọ run?
14
Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú Òkun, bí ohun tí ń rákò tí wọn ko ni alákòóso.
15
Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn sókè ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n ńlá rẹ̀; nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú.
16
Nítorí náà, ó rú ẹbọ sí àwọ̀n rẹ̀, ó sì ń sun tùràrí fún àwọ̀n ńlá rẹ̀ nítorí pẹ̀lú àwọ̀n rẹ̀ ni ó fi ń gbé ní ìgbádùn tí ó sì ń gbádùn pẹ̀lú oúnjẹ tí ó bá wù ú.
17
Ǹjẹ́ wọn yóò ha máa pa àwọ̀n wọn mọ́ ní òfìfo bí, tí wọn yóò sì pa orílẹ̀-èdè run láìsí àánú?
Settings