Gẹnẹsisi 10:18
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 18 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
15
Kenaani sì bí Sidoni àkọ́bí rẹ̀, àti Heti.
16
Àti àwọn ará Jebusi, àti àwọn ará Amori, àti àwọn ará Girgaṣi,
17
àti àwọn ará Hifi, àti àwọn ará Arki, àti àwọn ará Sini,
18
àti àwọn ará Arfadi, àti àwọn ará Semari, àti àwọn ará Hamati. Lẹ́yìn èyí ni àwọn ẹ̀yà Kenaani tànkálẹ̀.
19
Ààlà ilẹ̀ àwọn ará Kenaani sì dé Sidoni, lọ sí Gerari títí dé Gasa, lọ sí Sodomu, Gomorra, Adma àti Seboimu, títí dé Laṣa.
20
Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Hamu, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, àti èdè wọn, ní ìpínlẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.
21
A bí àwọn ọmọ fún Ṣemu tí Jafeti jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin: Ṣemu sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Eberi.
Settings