Skip to content
Esra 3:1-7

Àtúnkọ́ Pẹpẹ àti Ìmúpadà Ìjọsìn

Esra 3:1-7
1
Nígbà tí ó di oṣù keje tí àwọn ọmọ Israẹli sì ti wà nínú àwọn ìlú wọn, àwọn ènìyàn péjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ní Jerusalẹmu.
2
Nígbà náà ni Jeṣua ọmọ Josadaki àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli àti àwọn ènìyàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ pẹpẹ Ọlọ́run Israẹli láti rú ẹbọ sísun níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a ti kọ sínú ìwé òfin Mose ènìyàn Ọlọ́run.
3
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ẹ̀rù àwọn ènìyàn tí ó yí wọn ká ń bà wọ́n síbẹ̀, wọ́n kọ́ pẹpẹ sórí ìpìlẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì rú ẹbọ sísun lórí rẹ̀ sí Olúwa, ọrẹ àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́.
4
Nígbà náà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ, wọ́n ṣe àjọ àgọ́ ìpàdé pẹ̀lú iye ẹbọ sísun tí a fi lélẹ̀ fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.
5
Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun àtìgbàdégbà, ẹbọ oṣù tuntun àti gbogbo àwọn ẹbọ fún gbogbo àpèjẹ tí a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa, àti àwọn tí a mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá fún Olúwa.
6
Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní rú ẹbọ sísun sí Olúwa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ì tí ì fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀.
7
Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ní owó, wọ́n sì tún fi oúnjẹ, ohun mímu àti òróró fún àwọn ará Sidoni àti Tire, kí wọ́n ba à le è kó igi kedari gba ti orí omi Òkun láti Lebanoni wá sí Joppa, gẹ́gẹ́ bí Kirusi ọba Persia ti pàṣẹ.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 90 chars

Options