Skip to content
Esekiẹli 38:1-7

Esekiẹli 38:1-7

1
Ọrọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
2
“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí Gogu, ti ilẹ̀ Magogu; olórí ọmọ-aládé, Meṣeki, àti Tubali sọtẹ́lẹ̀ ní ìlòdì sí i
3
kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Gogu, olórí ọmọ-aládé, Meṣeki àti Tubali.
4
Èmi yóò yí ọ kiri, èmi yóò sì fi ìwọ̀ kọ́ ọ ní ẹnu, èmi yóò sì fà ọ́ jáde pẹ̀lú gbogbo ọmọ-ogun rẹ, àwọn ẹṣin àti àwọn agẹṣinjagun nínú ìhámọ́ra, àti ìpéjọ ńlá pẹ̀lú asà ogun ńlá àti kéékèèké, gbogbo wọn ń fi idà wọn.
5
Persia, Kuṣi àti Puti yóò wà pẹ̀lú wọn, gbogbo wọn yóò wà pẹ̀lú asà àti ìṣíborí wọn
6
Gomeri náà pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti Beti-Togarma láti jìnnàjìnnà àríwá pẹ̀lú gbogbo àwọn ọ̀wọ́ ogun rẹ̀—ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú rẹ̀.
7
“ ‘Múra sílẹ̀, múra tán, kí ìwọ àti gbogbo ìjọ náà péjọpọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí o sì pàṣẹ fún wọn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options