Esekiẹli 37:15-23
15
Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mi wá:
16
“Ọmọ ènìyàn, mú igi pátákó kan kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, ‘Tí ó jẹ́ ti Juda àti ti Israẹli tí ó ní àṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’ Lẹ́yìn náà, kí ó mú igi pátákò mìíràn kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, ‘Tí ó jẹ́ ti tí Josẹfu (tí ó túmọ̀ sí ti Efraimu) àti gbogbo ilé Israẹli tí ó ni àṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’
17
So wọ́n papọ̀ sí ara igi kan nítorí náà wọn yóò di ọ̀kan ní ọwọ́ rẹ.
18
“Nígbà tí àwọn ara ìlú rẹ bá béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Ṣé ìwọ kò ní sọ ohun tí èyí túmọ̀ sí fún wa?’
19
Sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò gba igi Josẹfu—èyí tí ó wà ní ọwọ́ Efraimu—àti ti ẹ̀yà Israẹli tí ó parapọ̀ mọ́ ọn, kí ó sì só papọ̀ mọ́ igi Juda, láti sọ wọ́n di igi kan ṣoṣo, wọn yóò sì di ọ̀kan ní ọwọ́ mi.’
20
Gbé igi pátákó tí ó kọ nǹkan sí i sókè ní iwájú wọn,
21
kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò mú Israẹli jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti lọ. Èmi yóò ṣà wọ́n jọ pọ̀ láti gbogbo agbègbè, èmi yóò sì mú wọn padà sí ilẹ̀ ara wọn.
22
Èmi yóò ṣe wọ́n ní orílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ náà, ní orí òkè Israẹli, ọba kan ni yóò wà lórí gbogbo wọn, wọn kì yóò sì jẹ́ orílẹ̀-èdè méjì mọ́, tàbí kí a pín wọn sí ìjọba méjì.
23
Wọn kì yóò sì tún fi àwọn òrìṣà wọn ba ara wọn jẹ́ mọ́, tàbí ohun ìríra wọn, tàbí ohun ìrékọjá wọn: ṣùgbọ́n èmi yóò gbà wọn là kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àgàbàgebè wọn, èmi yóò sì wẹ̀ wọn mọ́. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.
Settings