Esekiẹli 33:12-16
12
“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ rẹ, ‘Ìṣòdodo ti olódodo ènìyàn kì yóò gbà á nígbà tí òun bá ṣe àìgbọ́ràn, ìwà búburú ènìyàn búburú kì yóò mú kí o ṣubú nígbà tí ó bá yí padà kúrò nínú rẹ̀. Bí olódodo ènìyàn bá ṣẹ̀, a kò ni jẹ́ kí ó yè nítorí òdodo rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀.’
13
Bí mo bá sọ fún olódodo ènìyàn pé òun yóò yè, ṣùgbọ́n nígbà náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé òdodo rẹ̀ tí ó sì ṣe búburú, a kò ní rántí nǹkan kan nínú iṣẹ́ òdodo tí o ti ṣe sẹ́yìn; òun yóò kú nítorí búburú tí ó ṣe.
14
Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé, ‘Ìwọ yóò kú dandan,’ ṣùgbọ́n tí ó bá yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ti o sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí o yẹ.
15
Tí ó bá mu ògo padà, tí o sì da ohun tí o ti jí gbé padà, tí ó sì tẹ̀lé òfin tí ó ń fún ni ní ìyè, tí kò sì ṣe búburú, òun yóò yè dandan; òun kì yóò kú.
16
A kò ní rántí ọ̀kan nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti dá. Ó ti ṣe èyí tí ó tọ àti èyí tí o yẹ; òun yóò sì yè dájúdájú.
Settings