Skip to content
Esekiẹli 31:3-9

Esekiẹli 31:3-9

3
Kíyèsi Asiria, tí ó jẹ́ igi kedari ni Lebanoni ní ìgbà kan rí, pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka dáradára tí ó ṣẹ́ ìji bo igbó náà; tí ó ga sókè, òkè rẹ̀ lókè ni ewé tí ó nípọn wà.
4
Omi mú un dàgbàsókè: orísun omi tí ó jinlẹ̀ mú kí o dàgbàsókè; àwọn odo rẹ̀ ń sàn yí ìdí rẹ̀ ká, ó sì rán ìṣàn omi rẹ̀ sí gbogbo igi orí pápá.
5
Nítorí náà ó ga sí òkè fíofío ju gbogbo igi orí pápá lọ; ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn, wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
6
Ẹyẹ ojú ọ̀run kọ ilé sí ẹ̀ka rẹ̀ gbogbo ẹranko igbó ń bímọ ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀; gbogbo orílẹ̀-èdè ńlá ń gbé abẹ́ ìji rẹ̀.
7
Ọláńlá ní ẹwà rẹ̀ jẹ́, pẹ̀lú títẹ́ rẹrẹ ẹ̀ka rẹ̀, nítorí gbòǹgbò rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ sí ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi wà.
8
Àwọn igi kedari nínú ọgbà Ọlọ́run kò lè è bò ó mọ́lẹ̀; tàbí kí àwọn igi junifa ṣe déédé pẹ̀lú ẹ̀ka rẹ̀, tàbí kí a fi igi títẹ́ rẹrẹ wé ẹ̀ka rẹ̀, kò sí igi nínú ọgbà Ọlọ́run tí ó dà bí rẹ̀ ní ẹwà rẹ̀.
9
Mo mú kí ó ní ẹwà pẹ̀lú ẹ̀ka lọ́pọ̀lọ́pọ̀ tó fi jẹ́ ìlara àwọn igi gbogbo ní Edeni tí í ṣe ọgbà Ọlọ́run.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options