Skip to content
Esekiẹli 29:13-16

Esekiẹli 29:13-16

13
“ ‘Ṣùgbọ́n báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní òpin ogójì ọdún, èmi yóò ṣa àwọn ará Ejibiti jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi tí a fọ́n wọn ká sí.
14
Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Ejibiti padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Paturosi, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀.
15
Ibẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba tí ó rẹlẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọba, kì yóò sì gbé ara rẹ̀ ga mọ́ sórí àwọn orílẹ̀-èdè: nítorí èmi ni ó dín wọn kù, tiwọn kì yóò fi ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́.
16
Ejibiti kí yóò sì jẹ orísun ìgbẹ́kẹ̀lé fún ilé Israẹli mọ́ ṣùgbọ́n, yóò jẹ́ ìrántí fún àìṣedéédéé wọn, nígbà tí yóò bá wò wọ́n fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.’ ”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options