Esekiẹli 22:1-12
1
Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:
2
“Ọmọ ènìyàn ǹjẹ́ ìwọ yóò ha ṣe ìdájọ́ rẹ̀? Ǹjẹ́ ìwọ ha ṣe ìdájọ́ ìlú atàjẹ̀sílẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀ dojúkọ wọn pẹ̀lú gbogbo ìwà ìríra wọn.
3
Kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ìwọ ìlú ńlá tí ó mú ìparun wá sórí ara rẹ nípa títàjẹ̀sílẹ̀ ní àárín rẹ, tí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́ nípa ṣíṣe àwọn ère.
4
Ìwọ ti jẹ̀bi nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀, àti pé àwọn ère tí ó ṣe tí bà ọ́ jẹ́. Ìwọ tí mú ọjọ́ rẹ súnmọ́ tòsí, ìparí àwọn ọdún rẹ sì ti dé. Nítorí náà èmi yóò fi ọ ṣe ohun ẹ̀gàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè àti ohun ẹ̀sín lójú gbogbo ìlú.
5
Àwọn tí ó wà ní tòsí àti àwọn tí ó jìnnà sí ọ, yóò fi ọ ṣe ẹlẹ́yà, ìwọ ìlú ẹlẹ́gàn, tí ó kún fún làálàá.
6
“ ‘Wo bí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin ọba Israẹli tí ó wà nínú yín ti ń lo agbára rẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀.
7
Nínú rẹ wọn ti hùwà sí baba àti ìyá pẹ̀lú ìfojú tínrín; nínú rẹ wọn ti ni àwọn àlejò lára, wọn sì hùwàkiwà sí aláìní baba àti opó.
8
Ìwọ tí kọ àwọn ohun mímọ́ mi sílẹ̀, ìwọ sì ti lo ọjọ́ ìsinmi mi ní ìlòkulò.
9
Nínú rẹ ni àwọn ayannijẹ ènìyàn pinnu láti tàjẹ̀ sílẹ̀; nínú rẹ ní àwọn tí ó ń jẹun ní orí òkè ojúbọ òrìṣà, wọn sì hùwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.
10
Nínú rẹ ní àwọn ti kò bu ọlá fún àwọn àkéte baba wọn; nínú rẹ ni àwọn tí o ń bá àwọn obìnrin lò nígbà tí wọ́n ń ṣe àkókò lọ́wọ́, ní àsìkò tí a ka wọn sì aláìmọ́.
11
Nínú rẹ ọkùnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ìríra pẹ̀lú aya aládùúgbò rẹ̀, òmíràn bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ jẹ́, òmíràn sì bá arábìnrin rẹ̀ lòpọ̀ èyí tí í ṣe ọbàkan rẹ̀.
12
Nínú rẹ àwọn ènìyàn gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀; ìwọ gba èlé ìlọ́po láti mú aláìṣòótọ́ jèrè láti ara aládùúgbò rẹ nípa ìrẹ́jẹ. Ìwọ sì ti gbàgbé èmi; ni Olúwa Olódùmarè wí.
Settings