Esekiẹli 19:5-9
5
“ ‘Nígbà tí abo kìnnìún yìí rí pé ìrètí rẹ̀ sì jásí asán, ó mú ọmọ rẹ̀ mìíràn ó sì tún tọ́ ọ dàgbà di kìnnìún tó ní agbára.
6
Ó sì ń rìn káàkiri láàrín àwọn kìnnìún nítorí pé ó ti lágbára, o kọ ọdẹ ṣíṣe, ó sì pa àwọn ènìyàn.
7
Ó sì wó odi wọn palẹ̀ ó sì sọ àwọn ìlú wọn di ahoro. Ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé ibẹ̀ sì wà ní ìpayà nítorí bíbú ramúramù rẹ̀.
8
Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè dìde sí i, àwọn tó yìí ká láti ìgbèríko wá. Wọn dẹ àwọ̀n wọn fún un, wọn sì mú nínú ihò wọn.
9
Wọn fi ìwọ̀ gbé e sínú àgò, wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli, wọn fi sínú ìhámọ́, a kò sì gbọ́ bíbú rẹ̀ mọ́ lórí òkè Israẹli.
Settings