Skip to content
Esekiẹli 19:10-14

Esekiẹli 19:10-14

10
“ ‘Ìyá rẹ dàbí àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ̀; tí á gbìn sí etí odò ó, kún fún èso, ó sì kún fún ẹ̀ka nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
11
Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lágbára tó láti fi ṣe ọ̀pá àṣẹ ìjòyè, ó ga sókè láàrín ewé rẹ̀, gíga rẹ̀ hàn jáde láàrín ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka rẹ̀.
12
Ṣùgbọ́n ó fà á tu ní ìrunú, á sì wọ́ ọ lulẹ̀, afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn sì gbé èso rẹ̀, ọ̀pá líle rẹ̀ ti ṣẹ́, ó sì rọ iná sì jó wọn run.
13
Báyìí, a tún ún gbìn sínú aṣálẹ̀ ni ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tó ń pòǹgbẹ omi.
14
Iná sì jáde láti ọ̀kan lára ẹ̀ka rẹ̀ ó sì pa ẹ̀ka àti èso rẹ̀ run, dé bi pé kò sí ẹ̀ka tó lágbára lórí rẹ̀ mọ́; èyí to ṣe fi ṣe ọ̀pá fún olórí mọ́.’ Èyí ni orin ọ̀fọ̀ a o sì máa lo bí orin ọ̀fọ̀.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options