Esekiẹli 19:2-9
2
wí pé: “ ‘Èwo nínú abo kìnnìún ni ìyá rẹ̀ ní àárín àwọn kìnnìún yòókù? Ó sùn ní àárín àwọn ọ̀dọ́ kìnnìún ó sì ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.
3
Ó sì tọ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà, ó sì di kìnnìún tó ní agbára, ó kọ́ ọ láti ṣọdẹ, ó sì ń pa àwọn ènìyàn jẹ.
4
Àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì fi ẹ̀wọ̀n mú un nínú iho wọn. Wọn fi ẹ̀wọ̀n mu nu lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.
5
“ ‘Nígbà tí abo kìnnìún yìí rí pé ìrètí rẹ̀ sì jásí asán, ó mú ọmọ rẹ̀ mìíràn ó sì tún tọ́ ọ dàgbà di kìnnìún tó ní agbára.
6
Ó sì ń rìn káàkiri láàrín àwọn kìnnìún nítorí pé ó ti lágbára, o kọ ọdẹ ṣíṣe, ó sì pa àwọn ènìyàn.
7
Ó sì wó odi wọn palẹ̀ ó sì sọ àwọn ìlú wọn di ahoro. Ilẹ̀ náà àti àwọn olùgbé ibẹ̀ sì wà ní ìpayà nítorí bíbú ramúramù rẹ̀.
8
Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀-èdè dìde sí i, àwọn tó yìí ká láti ìgbèríko wá. Wọn dẹ àwọ̀n wọn fún un, wọn sì mú nínú ihò wọn.
9
Wọn fi ìwọ̀ gbé e sínú àgò, wọn mú un lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Babeli, wọn fi sínú ìhámọ́, a kò sì gbọ́ bíbú rẹ̀ mọ́ lórí òkè Israẹli.
Settings