Esekiẹli 13:10-11
10
“ ‘Wọ́n ti mú àwọn ènìyàn mi ṣìnà, wọ́n ní, “Àlàáfíà,” nígbà tí kò sí àlàáfíà, nítorí pé bí àwọn ènìyàn bá mọ odi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, wọn a fi amọ̀ àìpò rẹ́ ẹ, wọn ó sì fi ẹfun kùn ún,
11
nítorí náà, sọ fún àwọn tí ń fi amọ̀ àìpò rẹ́ ẹ àti àwọn tó fi ẹfun kùn ún pé, odi náà yóò wó, ìkún omi òjò yóò dé, Èmi yóò sì rán òkúta yìnyín sọ̀kalẹ̀, ìjì líle yóò ya á lulẹ̀.
Settings