Eksodu 9:13
Ń ṣàfihàn ẹsẹ 13 pẹ̀lú àyíká ọ̀rọ̀ tó yí i ká.
10
Nígbà náà ni wọ́n bú eérú gbígbóná láti inú ààrò, wọ́n dúró ní iwájú Farao. Mose sì ku eérú náà sínú afẹ́fẹ́, ó sì di oówo tí ń tú pẹ̀lú ìléròrò ni ara àwọn ènìyàn àti lára ẹran.
11
Àwọn onídán kò le è dúró níwájú Mose nítorí oówo ti ó wà lára wọn àti ni ara gbogbo àwọn ara Ejibiti.
12
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run sé ọkàn Farao le, kò sì gbọ́ ti Mose àti Aaroni, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún Mose.
13
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Dìde ni òwúrọ̀ kùtùkùtù, kí o sì tọ Farao lọ, kí o sì wí fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn Heberu wí, Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn bá à lè sìn mí,
14
nítorí nígbà yìí ni èmi yóò rán àjàkálẹ̀-ààrùn ti ó ní agbára gidigidi sí ọ, sí àwọn ìjòyè rẹ àti sí àwọn ènìyàn rẹ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé, kò sí ẹni bí èmi ni gbogbo ayé.
15
Ó ti yẹ kí n ti na ọwọ́ mi jáde láti kọlù ọ́ àti àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú ààrùn búburú ti kò bá ti run yín kúrò ni orí ilẹ̀.
16
Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni èmi ṣe mú ọ dúró, kí èmi kí ó le fi agbára mi hàn lára rẹ, àti kí a bá à le máa ròyìn orúkọ mi ká gbogbo ayé.
Settings