Skip to content
Eksodu 8:1-10

Eksodu 8:1-10

1
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Padà tọ Farao lọ kí ó sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni Olúwa wí: Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn ó bá à lè sìn mi.
2
Bí ìwọ bá kọ̀ láti jẹ́ kí wọn ó lọ, èmi yóò fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀pọ̀lọ́ kọlu gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ.
3
Odò Naili yóò kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀pọ̀lọ́. Wọn yóò gòkè wá sí ààfin rẹ, àti yàrá rẹ ni orí ibùsùn rẹ. Wọn yóò gòkè wá sí ilé àwọn ìjòyè rẹ àti sí ara àwọn ènìyàn rẹ, àti sí ibi ìdáná rẹ, àti sí inú ìkòkò ìyẹ̀fun rẹ.
4
Àwọn ọ̀pọ̀lọ́ yóò gun ara rẹ àti ara àwọn ìjòyè rẹ, àti ara gbogbo àwọn ènìyàn rẹ.’ ”
5
Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Sọ fún Aaroni, ‘Kí ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde pẹ̀lú ọ̀pá sí orí àwọn odò kéékèèké àti odò ńlá, àti sí orí àwọn àbàtà kí ó sì mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ gòkè wá sí ilẹ̀ Ejibiti.’ ”
6
Ní ìgbà náà ni Aaroni sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí àwọn omi Ejibiti, àwọn ọ̀pọ̀lọ́ sì wá, wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀.
7
Ṣùgbọ́n àwọn onídán ilẹ̀ Ejibiti ṣe bákan náà pẹ̀lú agbára òkùnkùn wọn. Àwọn náà mú kí ọ̀pọ̀lọ́ gún wá sí orí ilẹ̀ Ejibiti.
8
Farao ránṣẹ́ pe Mose àti Aaroni, ó sì sọ fún wọn pé, “Gbàdúrà sí Olúwa kí ó mú àwọn ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí kúrò lọ́dọ̀ mi àti lára àwọn ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ kí àwọn ènìyàn rẹ kí ó lọ láti rú ẹbọ sí Olúwa.”
9
Mose sọ fún Farao pé, “Jọ̀wọ́ sọ fún mi ìgbà ti èmi yóò gbàdúrà fún ọ àti àwọn ìjòyè rẹ àti fún àwọn ènìyàn rẹ, kí àwọn ọ̀pọ̀lọ́ wọ̀nyí bá lè lọ lọ́dọ̀ rẹ àti ní àwọn ilé yín tí wọn yóò sì wà nínú odò Naili nìkan.”
10
Farao wí pé, “Ni ọ̀la.” Mose sì dáhùn pé, “Yóò sì rí bí ìwọ ti sọ, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé kò sí ẹni bí Olúwa Ọlọ́run wa.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options