Eksodu 5:1-9
1
Lẹ́yìn náà ni Mose àti Aaroni tọ Farao lọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli sọ, ‘Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè ṣe àjọ mi ní ijù.’ ”
2
Farao dáhùn wí pé, “Ta ni Olúwa, tí èmi yóò fi gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, tí èmi yóò fi jẹ́ kí Israẹli ó lọ? Èmi kò mọ Olúwa, èmi kò sì ní jẹ́ kí Israẹli ó lọ.”
3
Lẹ́yìn náà ni wọ́n wí pé, “Ọlọ́run àwọn Heberu tí pàdé wa. Ní ìsinsin yìí, jẹ́ kí a lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú aginjù láti rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run wa, kí Ó má ba á fi àjàkálẹ̀-ààrùn tàbí idà bá wa jà.”
4
Ṣùgbọ́n ọba Ejibiti sọ wí pé, “Mose àti Aaroni, èéṣe ti ẹ̀yin fi mú àwọn ènìyàn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Ẹ padà sẹ́nu iṣẹ́ yín.”
5
Nígbà náà ni Farao sọ pé, “Ẹ wò ó àwọn ènìyàn náà ti pọ̀ sí ì nílẹ̀ yìí ní ìsinsin yìí, ẹ̀yin sì ń dá wọn dúró láti máa bá iṣẹ́ lọ.”
6
Ní ọjọ́ yìí kan náà ni Farao pàṣẹ fún àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn ti ń ṣe alábojútó iṣẹ́ lórí àwọn ènìyàn.
7
“Ẹ̀yin kò ní láti pèsè koríko gbígbẹ fún bíríkì sísun mọ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí; ẹ jẹ́ kí wọn máa wá koríko gbígbẹ fún ara wọn.
8
Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn ó ṣe iye bíríkì kan náà bí ì ti àtẹ̀yìnwá, kí ẹ má ṣe dín iye rẹ̀ kú. Ọ̀lẹ ni wọ́n, ìwà ọ̀lẹ yìí náà ló mú wọn pariwo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rú ẹbọ sí Ọlọ́run wa.’
9
Ẹ mú iṣẹ́ náà le fún wọn, kí wọn bá a le è tẹramọ́ iṣẹ́ wọn, ẹ má fi ààyè gba irọ́ wọn.”
Settings