Eksodu 16:1-7
1
Ìjọ àwọn ọmọ Israẹli mú ọ̀nà wọn pọ̀n kúrò ni Elimu, wọ́n dé sí ijù Sini tí ó wà láàrín Elimu àti Sinai, ni ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù kejì tí wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.
2
Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sì ń kùn sí Mose àti Aaroni ní ijù náà.
3
Àwọn ọmọ Israẹli wí fún wọn pé, “Àwa ìbá ti ọwọ́ Olúwa kú ni Ejibiti! Níbi tí àwa ti jókòó ti ìkòkò ẹran ti a sì ń jẹ ohun gbogbo tí a fẹ́ ni àjẹyó, ṣùgbọ́n ẹ̀yin mú wa wá sí inú ijù yìí láti fi ebi pa wá tí a ó fi kú.”
4
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Èmi yóò rọ òjò oúnjẹ láti ọ̀run wá fún yín. Àwọn ènìyàn yóò sì máa jáde lọ ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti kó ìwọ̀nba oúnjẹ ti ó tó fún oúnjẹ òòjọ́ wọn. Ní ọ̀nà yìí ni, èmi yóò fi dán wọn wò láti mọ bóyá wọn yóò máa tẹ̀lé ìlànà mi.
5
Ní ọjọ́ kẹfà, ki wọn kó ìlọ́po méjì èyí tiwọn ń ko ni ojoojúmọ́ tẹ́lẹ̀.”
6
Mose àti Aaroni sọ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ní ìrọ̀lẹ́, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ni ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá.
7
Ní òwúrọ̀, ẹ̀yin yóò ri ògo Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn tí ẹ kùn sí i. Ta ni àwa ti ẹ̀yin yóò máa kùn sí wa?”
Settings