Skip to content
Oniwaasu 9:1-6

Oniwaasu 9:1-6

1
Nígbà náà ni mo wá ronú lórí gbogbo èyí, tí mo sì parí rẹ̀ pé, olóòtọ́ àti ọlọ́gbọ́n àti ohun tí wọ́n ń ṣe wà ní ọwọ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kò sí ènìyàn tí ó mọ̀ bóyá ìfẹ́ tàbí ìríra ni ó ń dúró de òun.
2
Àyànmọ́ kan náà ni gbogbo wọn yàn—olóòtọ́ àti ènìyàn búburú, rere àti ibi, mímọ́ àti àìmọ́, àwọn tí ó ń rú ẹbọ àti àwọn tí kò rú ẹbọ. Bí ó ti rí pẹ̀lú ènìyàn rere bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ bí ó ti rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń ṣe ìbúra bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí pẹ̀lú àwọn tí ó ń bẹ̀rù láti ṣe ìbúra.
3
Ohun búburú ni èyí jẹ́ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn. Ìpín kan ṣoṣo ni ó ń dúró de gbogbo wọn, ọkàn ènìyàn pẹ̀lú kún fún ibi, ìsínwín sì wà ní ọkàn wọn nígbà tí wọ́n wà láààyè àti nígbà tí wọ́n bá darapọ̀ mọ́ òkú.
4
Ẹnikẹ́ni tí ó wà láàrín alààyè ní ìrètí—kódà ààyè ajá sàn dáradára ju òkú kìnnìún lọ!
5
Nítorí pé ẹni tí ó wà láààyè mọ̀ wí pé àwọn yóò kú ṣùgbọ́n òkú kò mọ ohun kan wọn kò ní èrè kankan mọ́, àti pé kódà ìrántí wọn tí di ohun ìgbàgbé.
6
Ìfẹ́ wọn, ìríra wọn, àti ìlara wọn ti parẹ́: láéláé kọ́ ni wọn yóò tún ní ìpín nínú ohunkóhun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options