Skip to content
Oniwaasu 5:1-9

Oniwaasu 5:1-9

1
Ṣọ́ ìrìn rẹ nígbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọ́run. Kí ìwọ kí ó sì múra láti gbọ́ ju àti ṣe ìrúbọ aṣiwèrè, tí kò mọ̀ wí pé òun ń ṣe búburú.
2
Má ṣe yára pẹ̀lú ẹnu un rẹ, má sọ ohunkóhun níwájú Ọlọ́run. Ọlọ́run ń bẹ ní ọ̀run ìwọ sì wà ní ayé, nítorí náà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ ní ìwọ̀n.
3
Gẹ́gẹ́ bí àlá tí ń wá, nígbà tí ìlépa púpọ̀ wà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ nígbà tí ọ̀rọ̀ bá pọ̀jù.
4
Nígbà tí o bá ṣe ìlérí sí Ọlọ́run, má ṣe pẹ́ ní mímúṣẹ, kò ní inú dídùn sí òmùgọ̀, mú ìlérí rẹ sẹ.
5
Ó sàn láti má jẹ́ ẹ̀jẹ́, ju wí pé kí a jẹ́ ẹ̀jẹ́ kí a má mu ṣẹ lọ.
6
Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ tì ọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀. Má sì ṣe sọ fún òjíṣẹ́ ilé ìsìn pé, “Àṣìṣe ni ẹ̀jẹ́ mi.” Kí ló dé tí Ọlọ́run fi le è bínú sí ọ, kí ó sì ba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ jẹ́?
7
Asán ni ọ̀pọ̀ àlá àti ọ̀rọ̀ púpọ̀. Nítorí náà dúró nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
8
Bí o bá rí tálákà tí wọ́n ń ni lára ní ojú púpọ̀, tí a sì ń fi òtítọ́ àti ẹ̀tọ́ rẹ̀ dù ú, má ṣe jẹ́ kí ó yà ọ́ lẹ́nu láti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹni tí ó wà ní ipò gíga máa ń mọ́ òṣìṣẹ́ tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ lójú ni, síbẹ̀ àwọn kan sì wà tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn méjèèjì.
9
Gbogbo wọn ni ó ń pín èrè tí wọ́n bá rí lórí ilẹ̀, àní ọba pàápàá ń jẹ èrè lórí oko.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options