Oniwaasu 3:1-8
1
Àsìkò wà fún ohun gbogbo, àti ìgbà fún gbogbo nǹkan ní abẹ́ ọ̀run.
2
Ìgbà láti bí àti ìgbà kíkú, ìgbà láti gbìn àti ìgbà láti fàtu.
3
Ìgbà láti pa àti ìgbà láti mú láradá ìgbà láti wó lulẹ̀ àti ìgbà láti kọ́.
4
Ìgbà láti sọkún àti ìgbà láti rín ẹ̀rín ìgbà láti ṣọ̀fọ̀ àti ìgbà láti jó,
5
ìgbà láti tú òkúta ká àti ìgbà láti ṣà wọ́n jọ ìgbà láti súnmọ́ àti ìgbà láti fàsẹ́yìn,
6
ìgbà láti wá kiri àti ìgbà láti ṣàì wá kiri ìgbà láti pamọ́ àti ìgbà láti jù nù,
7
ìgbà láti ya àti ìgbà láti rán ìgbà láti dákẹ́ àti ìgbà láti sọ̀rọ̀,
8
ìgbà láti ní ìfẹ́ àti ìgbà láti kórìíra ìgbà fún ogun àti ìgbà fún àlàáfíà.
Settings