Skip to content
Deuteronomi 4:32-40

Deuteronomi 4:32-40

32
Ẹ béèrè báyìí nípa ti àwọn ọjọ́ ìgbàanì ṣáájú kí a tó bí i yín, láti ìgbà tí Ọlọ́run ti dá ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé. Ẹ béèrè láti igun ọ̀run kan sí èkejì. Ǹjẹ́ irú nǹkan olókìkí báyìí: ti ṣẹlẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a ti gbọ́ irú u rẹ̀ rí?
33
Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn mìíràn tí ì gbọ́ ohùn Ọlọ́run rí, tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti gbọ́ tí ẹ sì yè?
34
Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ti gbìyànjú àti mú orílẹ̀-èdè kan jáde kúrò nínú òmíràn fúnra rẹ̀ rí, nípa ìdánwò, nípa iṣẹ́ àmì, àti iṣẹ́ ìyanu nípa ogun, tàbí nípa ọwọ́ agbára tàbí nína apá, àti nípa ẹ̀rù ńlá: gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe fún un yín ní Ejibiti ní ojú ẹ̀yin tìkára yín?
35
A fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn yín kí ẹ bá a lè gbà pé Olúwa ni Ọlọ́run. Kò sì sí ẹlòmíràn lẹ́yìn rẹ̀.
36
Ó jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, láti kọ́ ọ yín. Ní ayé, ó fi iná ńlá rẹ̀ hàn yín, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láti àárín iná wá,
37
torí pé ó fẹ́ràn àwọn baba ńlá yín, ó sì yan àwọn ọmọ wọn ní ipò lẹ́yìn wọn. Nípa ìwà láààyè àti nípa agbára ńlá rẹ̀ ni ó fi mú un yín kúrò ní Ejibiti.
38
Láti lé àwọn orílẹ̀-èdè tí ó tóbi tí ó sì lágbára níwájú yín; láti le è mú un yín wá sí ilẹ̀ wọn kí ẹ lè jogún rẹ̀ bí ó ti rí lónìí.
39
Ẹ gbà kí ẹ sì fi sọ́kàn lónìí pé Olúwa ni Ọlọ́run lókè ọ̀run lọ́hùn ún àti ní ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ níhìn-ín. Kò sí òmíràn mọ́.
40
Ẹ pa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ tí mo ń fún un yín lónìí; kí ó ba à le è yẹ yín, kí ẹ̀yin sì le è pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín ní gbogbo ìgbà.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options