Deuteronomi 16:13-17
13
Ẹ ṣe ayẹyẹ àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá ti kórè oko yín tí ẹ ti pakà tí ẹ sì ti fún ọtí tán.
14
Ẹ máa yọ̀ ní àkókò àjọ̀dún un yín, ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin, àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin yín, àti àwọn Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó tí ń gbé ní àwọn ìlú u yín.
15
Ọjọ́ méje ni kí ẹ̀yin kí ó fi ṣe ayẹyẹ fún Olúwa Ọlọ́run yín ní ibi tí Olúwa yóò yàn. Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín yóò bùkún un yín ní gbogbo ìkórè e yín, àti ní gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín, ayọ̀ ọ yín yóò sì kún.
16
Ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún ni kí gbogbo àwọn ọkùnrin rẹ kí ó farahàn níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ní ibi tí yóò yàn. Níbi àjọ àkàrà àìwú, níbi àjọ ọ̀sẹ̀, àti àjọ àgọ́ ìpàdé. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá sí iwájú Olúwa ní ọwọ́ òfo.
17
Kí olúkúlùkù ó mú ọrẹ wá bí agbára rẹ̀ ti tó, gẹ́gẹ́ bí ìbùkún Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ó fi fún un ọ̀.
Settings